Aafa kan, eni odun mejidinlogoji ti foju bale ejo majistreeti ilu Osogbo lori esun pe o lu obinrin kan ni jibiti egberun lona otadinlegberin naira.
Aafa ohun, Abdullateef Sanusi nileese olopa so pe o gba owo naa lowo Alhaja Ejide Salamatu lodun un 2011 lagbegbe Ostrich Bakery ni Olonkoro nilu Osogbo.
Gege bi Duro Adekunle to soju awon olopa se so, se ni Aafa Lati ni oun yoo fi owo naa seto fisa ati tikeeti irinajo sile mimo Meka fun Alhaja ohun, eleyii ti ko pada se.
Aafa Lati ni oun ko jebi esun naa, bee naa ni agbejoro re, Nnagite Okobie ro ile ejo lati faaye beeli sile fun un.
Ninu idajo re, Majistreeti Fatimah Sodamade gba beeli Aafa Lati pelu egberun lona eedegbeta naira ati oniduro kan ni iye kannaa.
O waa sun igbejo siwaju di ojo kokandinlogun osu kewa odun yii.
No comments:
Post a Comment