IROYIN YAJOYAJO

Friday, 15 September 2017

E ma tii dunnu ju o, iyanselodi tiwa si n tesiwaju - ASUU so fawon akeko LAUTECH

Agbarijopo egbe awon osise (ASUU) nile eko LAUTECH ti so pe ofo ojokeji oja ni oro tawon igbimo oludari ile eko naa so pe kawon akeko wole loni ojo keedogun osu kesan. 
Egbe ASUU ohun, nipase alaga won, Abiodun Olaniran salaye pe awon omo egbe oun ko gbo nnkankan nipa igbese tawon igbimo ohun gbe ati pe iyanselodi si n tesiwaju lodo tawon. 
Olaniran ni oun ko tie mo pe won ti kede iwole fawon akeko. O ni gbogbo nnkan tawon n tori e yanselodi nijoba ipinle Osun ati Oyo ko tii mojuto, idi si niyii to fi ni awon ko nii pada senu ise ni tawon. 
Lara nnkan tawon egbe ASUU n beere ni sisan owo osu mokanla tawon ijoba ipinle mejeeji je won, sisanwo ajemonu won, eto idojutofo fawon osise, owo igbega lenu ise ati bee bee lo. 
A oo ranti pe leyin osu mewa tawon akeko fi joko sile nigbimo oludari ile eko LAUTECH kede lana pe kawon akeko pada sinu ogba ileewe naa ati pe eko kiko yoo bere ni pereu lojoo Monde to n bo.

No comments:

Post a Comment