Tolulope Emmanuel
Osogbo
Gomina ipinle Osun, Ogbeni Rauf Aregbesola ti so pe ko senikeni to lowo ninuu abuku ti won fi kan komisanna re foro ibasepo agbegbe ti yoo lo laijiya.
Ojo melo kan seyin la fi to yin leti pe awon odo kan fiya je komisanna ohun, Onorebu Bola Ilori lasiko ipade apero kan to waye nipinle Ondo.
Sugbon bi ijoba ipinle Ondo se so pe se lawon asoju ti won wa sibi ipade apero naa latipinle Osun loo da wahala sile nibe, naa lawon kan so pe ounje tawon ara Osun n ja si lohun lo da wahala sile lojo naa.
Sugbon Aregbesola so pelu ibinu pe enikeni to ba na aja tisa ti na tisa naa niyen. O ni niwon igba to je pe gomina atawon eeyan ipinle Osun ni Ilori loo soju nibe, o ye kijoba ipinle Ondo seto aabo to peye fun un lohun.
Gomina fi kun oro re pe ko bojumu ki enikeni to ni ikunsinu pelu Ilori tele lo anfaani asiko to loo soju oun (Aregbesola) lohun lati huwa abuku naa sii.
Aregbesola waa ke si gbogbo awon agbofinro lati dide si oro naa, ki won si sa gbogbo awon ti won lowo ninuu jagidijagan ohun.
Bakannaa lo ni onilu irumi won to wa labe omi gbodo di wiwa jade lati foju winna ofin nitori pe iwa ti ko bojumu gbaa ni won hu.
Subscribe to:
Post Comments (Atom)
Ni iwoye temi, iya ti won fi je Onarebu Bola Ilori ko se lori ipa ti o ko nigba eto ibo abele egbe oselu APC lati yan oludije si ipo gomina Ipinle Ondo lodun to koja. Iroyin fi ye wa nigbanaa lohun wipe Ilori ko faramo jijawe olubori Barisita Rotimi Akeredolu gegebi asoju egbe naa ninu eto idibo ohun eyi ti o han gbangba gbangba si mutumuwa. Bakannaa, igbese ri bi ona lati fiye Ilori wipe ko si aye fun un lati du ipo gomina Ipinle Ondo lojo iwaju ti o ba tile ugbero lati se bee niwon igba ti o je wipe omo bibi Ilu Ondo ni Ipinle naa ni oun ise.
ReplyDeleteBakannaa, mo fi asiko yi ro awon gomina ipinle mejeeji lati jumo jiroro bi oro naa yoo se lo momi lokun igbagbe ki o maa baa da rogbodiyan miran sile laarin won. Omo iya kannaa saa ni won!
Kasa ma se dada
ReplyDelete