Iwadi ti fihan bayii pe latari ipa ti Komisanna fun Gomina Aregbesola lori oro ibasepo agbegbe, Honorebu Bola Ilori ko lasiko eto idibo gomina ipinle Ondo lodun to koja lo fa a tawon odo ipinle naa se fowo ba a.
Omobibi ipinle Ondo ni Bola Ilori sugbon latigba ti Gomina Aregbesola ti n jangudu lati dori aleefa nipinle Osun lo ti tele e, idi si niyen to fi je oludamoran lori oro ayika nigba saa akooko Aregbesola, to si tun je komisanna ni saa keji yii.
Lasiko ibo gomina to koja l'Ondo ninu eyi ti Rotimi Akeredolu ti jawe olubori ni Bola Ilori atawon omo egbe APC tinu n bi nigba naa loo darapo mo egbe AD eleyii ti opolopo gbagbo pe ohun ti Seneto Bola Tinubu ati Gomina Aregbesola fe ni won se nigba naa.
Sugbon lana ode yii ni Bola Ilori loo sojuu Gomina Aregbesola nibi ipade apero kan lori atunto orileede yii to waye nilu Akure. Awon oniroyin la gbo pe Ilori fee ba soro tawon odo naa fi kolu, koda, a gbo pe won fa aso komisanna naa ya ti won si n pariwo lee lori pe ki lo n wa ninuu APC.
Opelope awon olopa pelu awon agbaagba egbe tisele naa sojuu won ni won tete gba Ilori lowo awon odo tinu n bi ohun.
Amo sa, Bola Ilori ti so pe okan lara awon oloselu to wa nijoba nipinle Ondo lowolowo bayii lo ran awon odo naa si oun.
Subscribe to:
Post Comments (Atom)
Eleyi kodara to, ko ye Kosi iwa janduku mo ninu Oro oselu lorilede yi
ReplyDelete