IROYIN YAJOYAJO

Tuesday, 12 September 2017

Emi o kii se gomina ti yoo feju mo owo araalu, idagbasoke ipinle Ekiti lo je mi logun -Oluyede


Okan lara awon to n dupo gomina ipinle Ekiti labe asia egbe oselu APC Dokita Oluwamayokun Oluwole Oluyede ti ni idagbasoke ipinle Ekiti lo je oun logun, nitori naa oun kii se gomina ti yoo maa feju mo owo iluu.
Akosemose nipa eto-ilera ohun to waa darapo mo oselu bayii  ni won bi lodun merinlelaadota seyin niluu Ikere-Ekiti nijoba ibile Ikere Ekiti nipinle Ekiti.
Dokita Wole Oluyede, gege bawon eeyan se mo o, lasiko to n bawon akoroyin soro nipa ona ti yoo fi mu ayipada alailegbe ba ipinle Ekiti ti won ba yan an sipo gomina ninu eto idibo odun 2018 so pe asiko ti to bayii lati mu ipinle Ekiti kuro ninu ise ati osi tijoba to wa lode bayii fi n yangan.
Oluyede so pe niwongba tawon baba nla wa ba le se awon aseyori nla lawon lasiko won lai gbara le owo to n wole lati aapo ijoba apapo losoosu ko sohun to n di ipinle Ekiti lowo lati ma se iru e. O ni orisiriisi anfaani lawon to wa lode oni si n je lara awon aseyori tawon eeyan ohun ti gbe kale.
"Se ka so nipa eka eto eko ni, esin, eto ilera atawon mi-in bee bee lo to se pataki fun omoniyan bi kiko awon ileewe, ilewosan tabi awon ile-ijosin. Gbogbo nnkan wonyi ni won le se lai gbara le owo to n wole sapo awon ipinle lati aapo ijoba apapo losoosu."
Oluyede to benuate lu bi ijoba Gomina Ayodele Fayose se n so awon araalu deru nipinle Ekiti to si n mu won to loju titi lati maa pin ounje ti ko le tan isoro won fun won so pe ise ati osi lawon eeyan n gbe laruge nitori aimokan ati ailoye. O ni o seni laanu pe lode oni awon araalu ti waa gba ise ati osi gege bi igbe-aye won.
O so pe ipinle Ekiti naa le wo awokose ipinle Eko lati pese awon ohun ti yoo maa pawo wole fun won. O nipinle Eko n pa owo to le ni bilionu lona ogorun meta le mejilelaadorin, #372b losoosu labele ti Ekiti si n pa bilionu meji le ogorun kan milionu naira, o ni eleyii gan an je ohun ti ko je kijoba maa ri owo-osu osise san deede.
Dokita Oluyede so pe opolopo nnkan tawon oloselu mi-in n se lode oni lati dekun airi ise fawon odo, eyi ti won si n pe ni eto ironilagbara lo je etan lasan. O ni pinpin ero-ilota, okada ati bee lo ko le tan ise ati osi, ona kan ta a le fi bo ninu e ni ka jade kuro ninu ise ati osi ta a ti so ara wa si tipe.
Gege bo se so awon to loye ti won tun kawee ju lagbaye lawon omobibi ipinle Ekiti. O ni ohun gbogbo n lo daadaa laye atijo nigba ti ko si owo kankan to n wole lati aapo ijoba apapo, igbe-aye si dun gan an.
"Ohun to je mi logun ni pe mo fee igbe-aye irorun fawon odo wa, mo fee ki won le da wa laaye ara won, ki won maa pese ise fawon eeyan ki won si je oga ara won. Ta a ba wo awon orile-ede to ti goke agba lagbaye awon to n sise ara won, paapaa julo ise-owo lo maa ni owo ati oro julo.
"O je ohun ibanuje pe awon igbese tawon adari wa lonii n gbe ti je ko soro fawon odo lati le da duro maa sise ara won, mo fee pese agbegbe to dara ti yoo mu eto oro-aje gberu si I nipa ise ati eyawo fun okoowo. Mo ti bawon oga agba ileese nla ati banki to n satileyin fun ise agbe soro ti won si ti gba lati ran awon araalu lowo."
Nigba to n soro lori erongba re lori eto agbe, Oluyede so pe ise agbe je okan pataki nipinle Ekiti, atipe eto ogbin je ona kan to le mu idagbasoke ba ipinle yii, sugbon lode onii opolopo eeyan ko fee ma se agbe nitori pe igbagbo won ni pe awon agbe ki I l'owo lowo, oju talaka ni won fi n wo won, eyi ko si ri bee rara.
O ni owo to dara n'ise agbe lawon orile-ede to ti lami-laka lagbaye. O gba awon araalu niyanju lati ri ise agbe gege bi ohun to le pawo wole, o ni ki I se sise ise ofiisi nikan l'eeyan fi le l'owo tabi s'oriire laye.
Oluyede seleri lati da awon ileese nla nla kale tawon eeyan yoo ti maa sise agbe lawon ekun idibo meteeta to wa nipinle Ekiti. O loun ti ba ileese kan lorile-ede Germany to n pese awon ohun-eelo igbalode soro lati wa maa sise nipinle Ekiti.
Bakan naa lo tun so pe oun ti lo s'orilede United Kingdom, Germany, Australia, ati bee lo lati bawon omobibi ipinle Ekiti soro lori bi won yoo se waa da ise sile nipinle won lona ati mu idagbasoke ba ipinle Ekiti, opolopo won lo ni won setan lati se bee.
"Ipinle Ekiti nilo adari ti ko nii ko owo araalu sapo, ijoba wa ko nii fi owo araalu buta tabi je midin-midin, ohun to je wa logun ni sise ise fun ilu ati mimu idagbasoke ba ipinle Ekiti. Mo maa sise fun ipinle Ekiti to je pe awon eeyan yoo maa gbadura fun mi. Labe ijoba tiwa a maa ko awon odo, agbalagba, arugbo, osise atawon osise-feyinti mora. Owo-osu yoo maa lo deede ati lasiko, bii ajemonu lasan lowo to n wole lati aapo ijoba apapo yoo je."
O salaye pe ohun to n fa aisi aabo to peye ni bi alafo nla se wa laarin awon olowo ati otosi lawujo. O seleri lati mu igbe-aye derun fawon to ku die ka a to fun. O ni eleyii nikan lo le mu eto abo gbopon.
O ni ero toun ni pe Ida aadota lo ye ki won fun awon obinrin ninu awon ipo oselu, dipo Ida marundinlogoji ti won fun won bayii. Oluyede so pe Igba ti koja t'eeyan maa n ro awon obinrin seyin ninu eto idagbasoke ilu nitori pe won n kopa ribiribi lode onii.
"Nipinle Ekiti mo maa se ijoba to maa mu kawon eeyan wari ki won si maa gboriyin fawon obinrin. Mo maa ri I pe won n gba won senu ise daadaa. Awon obinrin yoo lanfaani lati so ohun ti won ba nifee si ati lati lo awon ohun amuye ati ogbon atinuda ti Olorun jogun fun won lati gberi lawujo, onikaluku ni yoo ni anfaani dogban-dogba, eto won ni.
O so pe bo tile je pe awon eeyan maa n wo ayeye asa ati isese bii Olosunta, Udiroko ati bee lo gege bi iborisa, sugbon asise nla gbaa ni. O lawon ayeye ta a so yii lawon baba nla wa maa n lo lati mu ibasepo to danmoran wa laarin won, nitori naa ayeye isese ati asa ko ni ipalara kankan to n se fun wa gege bi kristeni tabi musulumi, dipo bee o tun maa gbe oro-aje wa laruge ni nitori pe o maa n fa awon eeyan wa kaakiri agbaye lati waa wo bi isese ati asa Yoruba se dara to.
"Nile yoruba a ni awon idije bii ayo olopon, ija ati bee lo. A ni lati gbe eto asa ati isese ile wa laruge ka si yi bi a ti se n ronu atawon iwa wa pada. Eto asa ati isese gbodo je ohun to n pa owo wole fun wa. Fun apere ni Liverpool o ni ayeye kan ti won maa n se ti won n pe ni ayeye awon okun, iyen 'Festival of Seas' lede oyinbo. Awon to ba n pada bo lati inu okun ni won maa n se e fun.
Oluyede gba awon oloselu akegbe re nimoran lati maa gbepo pelu Ife. O ni iha Gusu Ekiti toun ti wa awon nijoba ibile to tobi julo l'Ekiti, bakan naa lawon si ni awon to koju osuwon lati dari ipinle yii, nitori naa Iha Gusu lo ye funpo gomina.
O dupe lowo awon akegbe re ti won jo n dupo gomina fun Ife ti won fi han. O ni: "Inu mi dun sawon ta a jo n dupo gomina ipinle Ekiti, mo si gboriyin fun won gidi, paapaa julo awa ta a wa lati iha Gusu ipinle Ekiti. Ti iru Onarebu Femi Bamisile, Seneto Gbenga Aluko, Ogbeni Muyiwa  Olumilua, Onimo-Ero Kola Alabi ati Ogbeni Debo Ajayi ba le wa sibi igbeyawo omo mi, lai ka pe a jo n dupo kan naa si, o fi han pe a ni owo fun ara wa, a si feran ara wa."

No comments:

Post a Comment