IROYIN YAJOYAJO

Monday, 11 September 2017

L'Osun, awon omo ajo otelemuye lu oniroyin lalubami

Alubami ni awon omo ajo otelemuye na awon oniroyin meji kan loni nilu Osogbo ninu ogba ile igbimo asofin ipinle Osun.
Awon osise ijoba ibile ti won n fehonuhan lorii pe kijoba apapo je kawon da duro ni won lo sile igbimo asofin lati fi oro naa to won leti la gbo pe awon oniroyin yii loo ba nibe.
Bi awon oniroyin ohun; Timothy Agbor tiwe iroyin The Point pelu Toba Adedeji tiwe iroyin Osun Defender se debe lomobinrin kan ti ko woso awon otelemuye loo ba won pe kini won n wa ati pe taani won.
Timothy da a lohun pe oniroyin lawon, bayii lomobinrin yii tun ni ko mu kaadi idanimo re jade, oro yii jo awon oniroyin yii loju nitori won ko mo iru eni to je. Bayii lawon naa beere pe komobinrin yii firaa re han.
Ibeere yii lo bi omobinrin yii ninu, ka too wi ka too fo, o ti bere sii rojo igbaju fun Timothy, bee niyen naa gbiyanju lati da eyokansoso pada.
Idi eyi ni won wa tawon otelemuye egbe re fi de ti won si bere sii din dundu iya fawon oniroyin mejeeji yii.
Koda, a gbo pe oro yii ya awon osise ijoba ibile loju, won si n pariwo pe awon oniroyin yii ko se nnkankan fawon otelemuye ti won fi n lu won bii eni lu bara.
Ni bayii, egbe oniroyin nipinle Osun ti ni iwa tawon olopa otelemuye naa hu ko bojumu rara nitori won ko huwa omoluabi lori oro naa.

No comments:

Post a Comment