Omokunrin eni odun mejidinlogun, Wasiu Wahab ladajo ile ejo majistreeti ilu Osogbo ti ni ko loo maa naju logba ewon ilu Ilesa titi tigbejo yoo fi bere lori oro e.
Wasiu ni won fesun kan pe o ji ilu ati aago to je ti Pasito Akintunde.
Ojo kewa osu kesan odun yii la gbo pe isele naa sele ni No 8, Olarinde street, lagbegbe Ofatedo nilu Osogbo.
Apapo owo ilu ati aago ti Wasiu ji, gege bi agbejoro fawon olopa, Inspekito Abiodun Fagboyinbo se wi, je egberun lona merinlelaadota naira.
Nigba ti won ka esun si Wasiu, eni ti ko ni agbejoro kankan to n duro fun un, leti, o ni oun jebi awon esun naa.
Adajo majistreeti naa, Olubukola Awodele ni kawon olopa loo fi olujejo pamo sogba ewon ilu Ilesa titi di ojo kokandinlogun osu kesan yii tigbejo yoo bere lori oro e.
Subscribe to:
Post Comments (Atom)
No comments:
Post a Comment