IROYIN YAJOYAJO

Thursday, 21 September 2017

Pasito Adepoju pariwo: Ihooho niyawo mi maa n gbe mi se'pe, o ti fo'go lorii mi ri

Pasito Lawrence Adepoju, eni odun marundinlogota ti so pe kile ejo koko-koko to wa ni Igando nipinle Eko tu igbeyawo olodun metalelogbon toun atiyawo oun, Racheal ka.
Adepoju ni abesekubiojo niyawo oun ati pe orisiirisii nnkan ija oloro niyawo oun fi maa n ja ti inu ba n bii.
Pasito yii ni gbogbo awon omobinrin inu ijo oun niyawo oun ti le lo tan pelu awawi wipe se loun n ni ife ikoko peluu won.
O ni eemeji otooto niyawo oun ti be oun lada lori, to si ti fo igo lori oun ri laitie ronu ti omo meta to ti wa ninu igbeyawo  naa.
Bakannaa naa lo so siwaju pe ti inu ba n bi iyawo oun se lo maa n boso sile ti yoo si maa sepe nlanla fun oun eleyii to nii pupo ninu awon epe naa lo ti n se bayii.
O waa ro ile ejo lati tu igbeyawo naa ka fun aabo emi re, ati ko le bo ninuu wahala obinrin naa.
Aare kootu naa, Ogbeni Adegboyega Omolola pase fun akowe kootu naa lati mu iwe ipejo lo fun obinrin naa ko le waa wi tenu e lojo kerinlelogun osu kewa odun yii.

No comments:

Post a Comment