Se ni gbogbo awon ti won gbo nnkan ti Moses Otimba se n gbe e sepe, bee ni won n pariwo pe ko gbodo bo ninu oran naa.
Omo odun metadinlaadota ni Moses to n gbe ni Yenogoa nipinle Bayelsa, agbere oju e lo mu ko fun aburo iyawo e, Joy Matthew to je omo odun mokandinlogun loyun.
Won se oro naa loku oru titi tiyen fi bimokunrin leyin osu kesan, leyin ti Mose ati Joy gbe omo tuntun naa kuro lodo noosi kan ti won bii si, won de ibi odo nla kan, Mose gba omo loowo Joy, o fowo di i nimu, ko lo ju iseju marun lo ti omo fi jade laye, bee lo gbe oku e ju sinuu koto kekere kan legbe odo.
Nigba ti eri okan ko je ki Joy gbadun lo so fun egbon e to je iyawo Mose, iyen lo foro naa to awon olopa leti ti won fi mu Mose.
Mose ko ba awon olopa jiyan pupo to fi jewo pe loooto ni, o ni iberu iyawo oun lo mu oun se nnkan naa ati pe oun ko mo iru igbese ti iya-iyawo oun le gbe lo je kawon se oro naa ni bonkele.
Nigba tawon olopa de eti odo yen, agbara ojo ti wo oku omo naa lo.
Komisanna olopa funpinle Bayelsa, Asuquo Amba ti so pe nigba tiwadi ba ti pari lori oro naa ni awon mejeeji yoo foju bale ejo.
Saturday, 9 September 2017
Home
/
Unlabelled
/
Ika ma lokunrin yii o! Moses fun aburo iyawo e loyun, o si pa omo naa lojo karun ti won bii
Ika ma lokunrin yii o! Moses fun aburo iyawo e loyun, o si pa omo naa lojo karun ti won bii
.Unknown
.
Subscribe to:
Post Comments (Atom)
Nkan nla!
ReplyDeleteOga O, nkan nla ni o
ReplyDelete