IROYIN YAJOYAJO

Monday, 25 September 2017

Nnkan nla! E wo iye tijoba ipinle Oyo lawon na lati doju ija ko Boko Haraamu

Adeola Tijani, Ibadan
Ajo to n gbogunti sise owo ilu basubasu,  Economic and Financial Crimes Commission ti bere iwadi lori iwe esun kan ti won ri gba pe ijoba ipinle Oyo se owo to le ni milioonu lona oodunrun naira basubasu
Ninu osu keta odun 2015 la gbo pe won pa a lase fun okookan awon alaga ijoba ibile metalelogbon to wa nibe lati gbe milioonu mokanla kale.
Pataki owo yii, gege bi won se so fawon alaga ohun nigba naa ni lati murasile ati lati doju ija ko awon omo iko Boko araamu ti won le fee wa da eto idibo odun naa ru.
A gbo pe ajo EFCC ti n ranse sawon alaga tajere oro naa si mo lori lati waa so tenuu won ti okan ninuu won si ti jewo pe milioonu mewa naira lokookan awon gbe fun eni to je alaga agbarijopo awon alaga, iyen ALGON nigba naa, bee ni won si ni kawon loo lo milioonu kookan to ku lorii bi gbogbo nnkan yoo se lo deede lasiko idibo naa.
Ohun to waa ru awon ti won kowe ranse si ajo EFCC loju ni pe ko seni to gburo awon Boko Haramu nigba naa, bee lawon alaga wonyii ko da owo naa pada sapo ijoba fun ilo awon araalu.

1 comment: