IROYIN YAJOYAJO

Wednesday, 20 September 2017

Olude Hijirah; komisanna Aregbesola ati oludamoran gomina tako araa won

Titi di asiko ti a n ko iroyin yii, awon osise ijoba nipinle Osun ko tii mo eyi ti won yoo tele ninu atejade meji to jade nirole oni lorii olude Hijirah eleyii ti won maa n gba lodoodun.
Odun 2012 nijoba Gomina Aregbesola ti bere sii ya ojo kan soto lati sami ibere odun naa ninu eyi to je pe awon osise yoo sinmi nile.
Ti odun yii to je Hijrah 1439 AH lo fee da ariyanjiyan sile bayii peluu bi komisanna feto iroyin, Ogbeni Adelani Baderinwa se so pe ojoo Jimoh, iyen ojo kejilelogun osu yii ni olude yoo wa fun odun naa.
Sugbon kiroyin naa too tutu ni oludamoran gomina lori eto iroyin, Ogbeni Sola Fasure ti gbe atejade miin jade pe ojoo Tosde tii se ojo kokanlelogun osu yii lolude Hijrah.
Atejade awon mejeeji naa ni won ni Gomina Aregbesola ranse ikini odun sawon musulumi, tawon mejeeji si ro awon musulumi lati samulo eko to wa ninuu hijrah.
Amo sa, boya Tosde lodun ni tabi Fraide, ko tii seni to ye, eleyii si so ijoba di elenumeji loju awon araalu.


No comments:

Post a Comment