IROYIN YAJOYAJO

Tuesday, 31 October 2017

Adajo ti ko ni ebo leru ni Adeigbe - OSAF


Tolulope Emmanuel, Osogbo

Egbe awon omobibi ilu Osogbo kan, Osogbo Affairs Forum (OSAF) ti gbosuba kare fun adajo ile ejo giga ipinle Osun to feyinti loni, Onidajo Moshud Adekunle Adeigbe.

Ninu atejade kan ti alaga ati akowe egbe naa, Omooba Hameed Oyegbade pelu Ogbeni Abdulrahman Okunade fi sita ni won ti ki Adeigbe kuu ogun ajaye.

Atejade naa sapejuwe Adeigbe gege bii adajo to we yan kainkain paapa lasiko yii ti orisiirisii asiri n tu nipa iwa ibaje to ti di ewu fun opolopo adajo lorileede yii.

Won ni Adeigbe, eni to di adajo lodun 2006 fi oruko rere ati iwa rere sile leka eto idajo nipinle Osun, bee ni ko ni ariwisi kankan bo tile wu ko mo titi to fi feyinti yii.

OSAF ni akinkanju ti kii fi ise re sere rara ni Onidajo Adeigbe ati pe pelu ooto inu lo fi sise, ti eri maa je mi niso naa si wa nipa e.

Won waa ro Adeigbe lati lo ogbon ati iriri to ti ni lenu ise oba fun idagbasoke ilu Osogbo tii se ilu abinibi re.

No comments:

Post a Comment