Ayinde Samuel, Ibadan
Inu ibanuje nla lawon molebi omokunrin kan, eni odun metadinlogoji wa bayii pelu bo se pokunso sinu ilee re lana.
Adebisi Shina la gbo pe o n sise okada, bee lo si niyawo meji, to si ti bimo meta.
Idaji ana lawon araale re lagbegbe Okeseni nilu Ibadan dede ba okuu re nibi to ti n mi dirodiro, ti emi si ti jade lara e ki won too debe.
Iwadi fihan pe lati ojometa kan lomokunrin naa ti n saroye nipa bi oro aje se denukole fun un to si nira lati rowo jeun, ka too wa so itoju awon omo e.
Bee lawon kan ladugbo re so pe o see se ki okunrin naa je awon kan lowo tawon yen si n fitina emi e lo se kuku para e.
No comments:
Post a Comment