Adeola Tijani, Ibadan
Adajo ile ejo giga kan nipinle Oyo, Muntar Abimbola ti so pe ki Arabinrin Yewande Oyediran eni to seku pa oko re, Lowo Oyediran Ajanaku loo sewon odun meje.
Akooko ewon naa ni adajo ni yoo bere lati ojo kerindinlogbon osu keji odun 2016 tigbejo ti bere lori esun ti won fi kan Yewande to je agbejoro nileese eto idajo nipinle Oyo.
Ojo kesan osu keji odun 2014 ni Lowo, omobibi ilu Gbongan nipinle Osun segbeyawo alarinrin pelu Yewande Oyediran, sugbon igbeyawo naa ko tii leso kankan titi ti Lowo fi jade laye.
Venerable ni baba Yewande ninu ijo kan nilu Ibadan, ilu
Ibadan si lawon tokotaya yii n gbe ko too di wipe ede aiyede kan be sile laarin won lojo kinni osu keji odun 2016 eleyii to yori si bi Yewande se gun un
lobe pa nidaji ojo keji osu keji naa.
Ojoo Monde, ogunjo osu keta odun 1978 ni won bi Adebayo Oyelowo
Oyediran Ajanaku sinu idile Omooba Oyediran Ajanaku tilee Olujide ni
Owoope nilu Gbongan. O lo sileewe Ansarudeen Primary School, Ayepe
nilu Gbongan ko too koja si Olufi High School nilu naa.
Leyin to pari lo loo keko nipa ise agbe, General Agriculture) nileewe Lagos state Polytechnic, nigba to si gba iwe eri onipele akoko, iyen OND nibe
lodun 1997 lo koja sileewe Obafemi Awolowo University nilu Ileefe nibi
to ti keko nipa Agricultural Economics.
Bo tile je pe orileede Canada lo wa lokan re lati kekere lati lo
sugbon orileede France ni eleda re ro mo lodun 2006, o lo sileewe
University of Grenoble ni France nibi to ti keko nipa Management and
Finance, nibe naa lo ti pade oreminuu re, Ogbeni Mikkel ki won too jo
di alajosisepo ti won si da ileese COZACAN Nig. Ltd sile lodun 2013.
Sugbon gbogbo awon molebi re ni won so nigba naa pe latigba to ti fe Yewande niyen ko je ko rojuu ebi mo, bee ni ko ni ifokanbale ninu igbeyawo naa.


No comments:
Post a Comment