Tolulope Emmanuel, Osogbo
Latari bi Elijah Adediran se so pe oun jebi esun ole jija ti won fi kan an ti ko si si ikaanu loju e, adajo ile ejo majiatreeti ilu Ileefe ti pase pe ko loo lo odun marun gbako logba ewon laifaaye faini sile fun un.
Esun meji otooto ni won tori e gbe Elijah lo sile ejo, awon esun ohun ni idite huwa buburu ati ole jija, sugbon Elijah ni oun ko jebi esun akooko, amo oun jebi esun keji.
Gege bi agbejoro to soju awon olopa, Inspekito Emmanuel Abdullahi se so funle ejo, ojo kokanlelogun osu kokanla odun yii ni Elijah loo ka Adiatu Ganiyu mole, to si ja a lole.
Nnkan aago meje aaro lolujejo huwa naa lagbegbe Oke-Ogbo nilu Ileefe.
Lara awon nnkan ti Elijah ji nile Adiatu ni faanu ti won maa n so mo oke ile (ceiling fans) meji, waya ina eleyio ti apapo owo won je egberun lona ogorun naira.
Abdullahi ni iwa to buru ni olujejo hu ati pe o nijiya labe ofin iwa odaran tipinle Osun.
Nigba to n gbe idajo re kale, Majistreeti Olalekan Ijiyode ni olujejo ko kaanu iwa to hu rara, o si dabi eni pe iwa naa ko nitumo loju e.
Ijiyode waa pase pe ki won loo fi Elijah omo odun meedogbon pamo sogba ewon ilu Ilesa fodidi odun marun gbako laifaaye faini sile fun un ko baa le je eko fawon odo bii tie.
O ni ki won mu un wa sile ejo lojo kejila osu to n bo fun igbejo lori esun akooko to so pe oun ko jebi e.

No comments:
Post a Comment