Tolulope Emmanuel, Osogbo
O see se ki apa kan ninu egbe oselu PDP eyi ti Onorebu Soji Adagunodo n dari e nipinle Osun begi di ipade apapo egbe naa ti yoo waye lojo kesan osu kejila odun yii.
Ohun to fa igbese yii gege bi a se gbo ni bi won se so pe iyanje wa ninuu ifowowewo, iyen harmonisation ti awon adari egbe so pe ki won se nipa awon ti yoo sojuu won nibi ipade naa.
Lati nnkan osu meji ni wahala ti n wa laarin awon abala ti Adagunodo ati ti Faforijin, idi si niyii ti oro idibo won ni woodu ati tijoba ibile ko fi lojutu.
Awon ti Adagunodo n fesun kan ti Faforijin pe won fe lo ona arumoje gba ipo alaga egbe l'Osun, won si so pe idibo gan an lawon fe lati woodu titi de ijoba ibile lati le yan alaga won.
Amo sa, awon ti Adagunodo so pe iyanje wa ninu gbogbo igbese tawon alase egbe n gbe, idi niyen ti won fi ni awon ko nii kopa nibi ipade naa eleyii ti won yoo fi yan alaga apapo egbe naa lorileede yii.

No comments:
Post a Comment