IROYIN YAJOYAJO

Thursday, 2 November 2017

Adanu nla ni iku Jide Tinubu je - Aregbesola


Tolulope Emmanuel

Gomina ipinle Osun, Ogbeni Rauf Aregbesola ti sapejuwe iku to wole mu akobilokunrin fundile Asiwaju Bola Tinubu gege bii adanu nla.

Ninu atejade kan ti gomina fi sita nipase akowe iroyin re, Sola Fasure, Aregbesola ni iku agbejoro naa je ibanuje fun oun lopolopo nitori pe omokunrin to jafafa, to si mo nnkan to n se ni oloogbe naa.

O ni ohun ti ko dara ni ki omo fi awon obi re saye lo, idi niyen toun fi kedun pelu idile asaaju egbe oselu APC ohun nitori oun mo pe atemora loro iku omo won naa je.

O waa gbadura, loruko idile re ati loruko gbogbo awon omobibi ipinle Osun pe ki Allah tu idile naa ninu, ko si te Oloogbe Jide Tinubu safefe rere.

No comments:

Post a Comment