Tolulope Emmanuel, Osogbo
Gomina ipinle Osun tele, Omooba Olagunsoye Oyinlola ti ranse ibanikedun si Asiwaju Bola Ahmed Tinubu lori iku omo re, Jide.
Omooba Oyinlola sapejuwe ikuu Agbejoro Jide, eleyii to waye lojoo Tusde to koja gege bii eyi to ba gbogbo eeyan lojiji to si banininuje lopolopo.
O ni iku naa je ogbe okan to jin pupo eleyii ti ko see sakawe rara pelu bi itanna omokunrin naa se wo losangangan.
Oyinlola waa ro Tinubu lati fi oro Olorun tu araa re ninu pe Oun nikan lo le fun ni, to si le gba a.
O sadura pe ojuu Asiwaju Tinubu ko nii ribi mo, bee ni ko nii sofo mo lori awon omo to ku.
No comments:
Post a Comment