IROYIN YAJOYAJO

Thursday, 30 November 2017

Adeyeye ju bombu oro ! O ni owo tawon Seneto n gba losu ti poju


Seneto to n soju awon eeyan ekun aaringbungbun Osun nile igbimo asofin agba orileede yii, Olusola Adeyeye ti ni lara nnkan to n ko ba oro-aje orileede yii ni owo goboi tawon Seneto atawon omo ile igbimo asofin apapo n gba losoosu.

Lasiko ijiroro ile asofin lori eto isuna onitirilioonu mejo ati die naira to wa fun odun 2018 eleyii ti Aare Buhari gbe siwaju ile ni Adeyeye ju bombu oro naa.

O ni o ya oun lenu bi awon asofin kan se n pe fun ki won mu adinku ba owo isuna naa laimenuba pe ki adinku ba owo osu ati ajemonu won.

Adeyeye ni ti adinku yoo ba ba owo eto isuna ti Aare gbe kale, ijoba gbodo koko wa ona lati din owo osu ati ajemonu awon asofin agba ati ti apapo.

Se lawon asofin to ku pariwo lasiko ti Adeyeye n soro yii, ti won si ni orin igbeyawo lo n da nibi isomoloruko.

No comments:

Post a Comment