Tolulope Emmanuel, Osogbo
Ileese ti won n pe ni Osun State Investment Company (OSICOL) ni won ti yi oruko re pada di Omoluabi Holdings Limited (OHL) bayii.
Gege bi alakoso ileese naa, Dokita Tunde Faleye se so fawon oniroyin, idagbasoke oniruuru lo ti ba ileese naa latigba ti Gomina Aregbesola ti dori aleefa isakoso nipinle Osun.
Faleye ni nnkan milioonu lona oodunrun naira nileese naa n dari ko too di pe Aregbesola de sugbon to ti le ni bilioonu meta ataabo naira bayii.
O fi kun oro re pe opolopo anfaani nijoba Gomina Aregbesola ti silekun re sile funleese naa eleyii to n mu kileese ohun maa gbile sii lojoojumo.
Lara awon okoowo ti ileese Omoluabi Holdings Limited tun ti n kopa, gege bi Faleye se wi ni epo-robi, adiye sinsin lona igbalode ati ise ogbin.
O waa ro awon ipinle yooku lati sawokose ipinle Osun nipa didawole awon nnkan ti yoo maa mowo wole fun won yato si ki won maa rogboku lejoba apapo.


No comments:
Post a Comment