Ijoba ipinle Ondo labe isakoso Gomina Rotimi Akeredolu ti so pe oun ko lagbara lati maa san owo idanwo awon akekojade ileewe girama, iyen WAEC nipinle naa mo.
Leyin ipade awon igbimo alase ipinle naa to waye lojoo Wesde ni komisanna feto eko l'Ondo, Femi Agagu ti ni igbese yii ko nii se pelu eto eko ofe to n lo lowo lati ileewe alakobere de girama.
Agagu ni ijoba yoo gbe igbimo kan kale laipe yii eleyii ti yoo maa ri si bi owo yoo se maa wole fun lilo eto eko nipinle naa.
O ni lati asiko yii lo, gbogbo awon agbaagba nipinle naa yoo maa san egberun kan naira gege bii owo idagbasoke eto eko.

No comments:
Post a Comment