IROYIN YAJOYAJO

Thursday, 23 November 2017

Ipinle Osun fee gbalejo ipade apero awon odo lekun Gusu Iwo-oorun orileede yii


Tolulope Emmanuel, Osogbo

Gomina lati ipinle mefa lekun Gusu Iwo oorun orileede yii nireti wa pe won yoo pejo silu Osogbo losu to n bo lati se alakale ona ti ibasepo to dan moran yoo se wa laarin awon odo agbegbe yii.

Eto naa, eleyii ti won pe ni 2017 Regional Youth Summit ni yoo waye laarin ojo kejila ati ojo ketala osu kejila odun yii.

Gege bo se wa ninu atejade kan ti oluranlowo agba fun Gomina Aregbesola lori oro elekunjekun, Ogbeni Wale Alabi fowo si, awon gomina ipinle Oyo, Osun, Ekiti, Ogun, Ondo, Lagos ni won yoo wa nibi eto naa ti yoo waye ni Atlantis Civic Center nilu Osogbo.

Wale Alabi ni akori gbooro ti won yoo lo fun eto naa ni "West 2040: Productivity, Prosperity and Peace".

Eto olojo meji naa, gege bi Alabi se so, yoo tubo si oju awon odo agbegbe yii si ona ti won yoo gba fowosowopo fun itesiwaju ati idagbasoke ipinle kookan yo wa ni ekun yii.


No comments:

Post a Comment