IROYIN YAJOYAJO

Friday, 17 November 2017

Alaileko ni oloselu to ba ko oro Oloye Bisi Akande danu - APC



Tolulope Emmanuel, Osogbo

Agbarijopo awon odo  kan ninu egbe oselu APC nipinle Osun ti won pe oruko ara won ni Integrity Forum ti so pe alaileko ati alailoye ni oloselu to ba ni ti Oloye Bisi Akande bawo nipinle Osun.

Egbe naa, nigba to n fesi si atejade kan ti egbe Leadership Factory gbe jade laipe yii nipase alakoso re, Charles Adeyemi wipe ki enikeni mase so pe ihja ibikan ni ki gomina ti yoo gbapo lowo Gomina Aregbesola ti wa.

A oo ranti pe laipe yii ni Oloye Bisi Akande so pe laifi ti ojusaju se, ekun Iwo Oorun ipinle Osun ni ipo gomina ipinle Osun to si nitori awon nikan ni won ko tii de ori aleefa naa bii ti awon ekun to ku yato si osu die ti Oloogbe Isiaka Adeleke lo nibe.

Sugbon egbe Leadership Factory ni ona lati du awon oludije kan lanfaani lati fi erongba won han funpo naa ni oro ohun ati pe ko si nnkan to jo bee lasiko olaju ti a wa yii, bee ni won ni awon ko nii gba igbese naa laaye.

Idi niyi ti egbe Integrity Forum nipase alakoso won, Ogbeni Adeyinka Adeola fi ni oro ti egbe naa so ju enu oloselu to nibowo fun agba lo.

Won ni "Ti a ba n soro oselu nipinle Osun, ko seni to le fi owo ro ogbon Oloye Akande seyin. Egbe APC mo pe iha Ariwa ni ipo aare kan lodun 2015 lo je ki won mu Aare Buhari. Lodun 2014 ti a tun Gomina Aregbesola yan, iha Ila oorun ipinle Osun ni gbogbo egbe oselu alatako ti loo mu awon oludije won nitori won mo pe agbegbe yen lo to si.

Bo tile je pe ko si akosile re ninu iwe ofin egbe, sibe ko seni ti ko mo pe ireje lo maa n fo egbe, idi si niyii ti baba wa ti a nigbagbo ninu e gidigidi fi so pe iha Iwo-oorun lo leto lati fa oludije sile.

"Ijoloju lo je fun wa pe awon omo kekeke ti won sese n dide ninu oselu le maa gba kawon kan lo awon lati da omi alaafia ti Olorun ti fun Gomina Aregbesola lanfaani lati gbe kale nipinle Osun ru.

"Sugbon a mo pe enikeni to ba fee dagba ninu oselu yoo setan lati teriba labe ibawi agba, paapa ko nii yi oro ti iru Oloye Akande ba so ninu iriri won pada".

Won waa ro Gomina Aregbesola lati de fila mawobe si oro rirun ti enikeni ba n so ati pe gboingboin lawon wa leyin isejoba re titi ti yoo fi ru eru naa laruso lodun to n bo.

No comments:

Post a Comment