IROYIN YAJOYAJO

Saturday, 18 November 2017

L'Osun, onorebu wo gau ; won lo gbe ise akanse ijoba ibile meta lo sile e l'Osogbo


Tolulope Emmanuel, Osogbo

Awon eeyan agbegbe ijoba ibile Ila/Boluwaduro ati Ifedayo ti so pe awon yoo ti ese bonuu sokoto kannaa pelu asofin to n soju awon nile igbimo asofin apapo orileede yii, Onorebu Julius Olufemi Fakeye ti ko ba salaye ohun to fa a to fi gbe ise akanse to foruko agbegbe naa gbe jade lo sile to ko silu Osogbo.

Fakeye lo gbe ise akanse to wa lati dena omiyale agbara ya soobu eleyii ti ileese Messrs Westfield Construction Limited, Abuja n se to si je ti awon eeyan agbegbe to n soju lo silee re to wa ni Low Cost Housing Estate, lagbegbe Kunfayakun nilu Osogbo.

Aafa Yakubu to je omobibi ilu Ila, to si tun je adari ninu egbe oselu APC lagbegbe naa so pe ijoloju ni nnkan ti Onorebu Fakeye se ohun je fun gbogbo awon.

O ni "emi o tii ri keeyan laya to beyen ri latigba ti mo ti n se oselu. Bawo leeyan yoo se fi oruko awon eeyan to dibo fun un gbe ise akanse to wa lati oofiisi akowe agba funjoba apapo orileede yii jade, ti yoo si gbe iru ise bee lo silu miin to kole si ?

"O dabi eni pe awon asofin yii fee maa mu wa lego, o tun laya lati gbe patako ajuwe to toka si ibi to ye ki ise naa wa sibe, ah, iwa aikakun pata gbaa lo wu, o si ye ka bii leere ejo lori e, mo mo pe awon adari egbe wa nipinle yii naa n ri nnkan to n lo".

Omo egbe oselu PDP kan to n gbe nilu Oke-Ila, Alagba Ayodele so pe ohun mo pe agbegbe awon ni pipe fun idapada asofin to ba siwa hu yoo ti bere nipinle Osun.

O ni "Se eyin naa ri nnkan ti egbe APC n se fun wa bayii ?  Ko si ibi ti a ko ti nilo ise akanse yen nijoba ibile meteeta, bawo waa ni asofin to ni oun n soju wa yoo se huwa ika beyen.

"Se ilu Osogbo wa lara awon eeyan to n soju nile igbimo asofin apapo ni abi ibe ni won ti dibo fun un ?  To ba je pe asofin egbe oselu PDP lo se bee, won a ti maa sunkun kaakiri aye".

Sugbon Onorebu Fakeye ko jiyan oro naa nigba tawon oniroyin pe e lorii foonu. Ohun to so ni pe ise akanse naa wa lati mu idagbasoke ba gbogbo ipinle Osun ni ati pe awon ota oun ni won n pariwo re kaakiri.



No comments:

Post a Comment