IROYIN YAJOYAJO

Wednesday, 1 November 2017

Baba Ghana to n tagbo l'Osun ni owo toun o fi wo moto pada si Ghana loun n wa


Tolulope Emmanuel, Osogbo

Owo ileese olopa ipinle Osun ti te baba agba omo orileede Ghana, eni aadorin odun kan, Samuel Agjei lori esun pe o n gbin igbo, o si tun n ta igbo.

Bakan naa ni won mu Samuel Sule ati lanloodu won, Sule Adeyemo lori esun kannaa.

Gege bi komisanna ileese olopa, Adeoye Fimihan se so baagi igbo nlanla marun ni won ka mo Agjei lowo lojo ti owo te awon afurasi ohun.

Sugbon baba arugbo yii ni ogun odun seyin loun ti de Naijiria ati pe owo toun yoo fi wo moto pada si orileede Ghana loun n wa toun fi sadehun lati ba eni to ni oko igbo naa sise fun odun kan.

Samuel Sule ni tie so pe isee telo oriirin loun n se koun too salabapade Agjei tawon jo je omo orileede Ghana eni to ni koun waa ran oun lowo ninu oko naa fun ojo marun pere ki owo too te awon.

Sugbon Adeoye ni ni kete tiwadi ba ti pari lorii won ni won yoo foju bale ejo.

No comments:

Post a Comment