IROYIN YAJOYAJO

Wednesday, 1 November 2017

Nitori inawo isinku baba-iyawo mi ni mo se ji aburo oga mi gbe - Williams


Sinmiloluwa Adigun

Williams Olowolabi ti jewo funleese olopa ipinle Eko pe nitori owo toun fee fi sinku baba-iyawo oun loun se pinnu lati ji aburo iyawo oga oun gbe koun le rowo gba lowo oga oun.

Williams, eni odun mejidinlogoji salaye pe oun ti koko beere fun eyawo lowo oga oun sugbon ti ko fun oun, idi niyen toun fi pe awon ore oun meji, Akin Adedamola ati Teluwo lati jo sise naa pelu ibon ilewo kan toun ya.

O fi kun oro re pe lojo kokanlelogun osu kewa odun yii loun dogbon tan aburo iyawo oga oun, Chukwudumebi pelu afesona re, Rebecca lo si ile kan lagbegbe Ogijo nibi tawon ti won mo.

O ni milioonu lona ogun naira lawon so fun won pe ki won beere lowo oga oun pelu iyawo re sugbon nigba tawon rii pe ise naa ko dahun daada lawon tu won sile.

Williams ni iyalenu lo je fun oun pe awon olopa ti loo mu iyawo ati omo oun nipase bee lowo saa fi te won.

Amo sa, komisanna ileese olopa ipinle Eko ti ni awon afurasi naa yoo foju bale ejo.

No comments:

Post a Comment