Tolulope Emmanuel, Osogbo
Lara akitiyan ijoba ipinle Osun lati mu ki eto okoowo rugogo sii fawon araalu, egberun meta laarin awon olokoowo nlanla ati kekeke ni won yoo lanfaani eyawo eleyii ti ko tii si iru e ri nipinle Osun.
Igbakeji aare orileede yii, Ojogbon Yemi Osinbajo nireti wa pe yoo pin sowedowo fawon olokoowo ohun lojoo Tusde ose yii eleyii to wa lara alakale eto ti won fi n sayeye odun keje ti Gomina Aregbesola de ori aleefa nipinle Osun.
Gege bi komisanna feto iroyin l'Osun, Onorebu Lani Baderinwa se so, komisanna feto okoowo nipinle Osun, Onorebu Ismail Jayeoba Alagbada ni yoo ba Ojogbon Osinbajo, eni tireti wa pe o n bo pelu minista foro okoowo ati karakata lorileede yii, Okechukwu Enelama koworin lo sibi eto naa.
Atejade ohun ni eto eyawo naa rorun pupo, yoo si fun awon olokoowo lanfaani lati ri owo sise eleyii ti yoo tun mu iyato ba eto karakata kaakiri ipinle Omoluabi.
O ni ijoba apapo lo gbe anfaani naa kale eleyii tijoba Gomina Aregbesola ri gege bi eyi ti yoo ko oriire ba awon eeyan ipinle re, idi niyii to fi fa ire naa wa si Osun.
O waa ro awon araalu lati tubo maa fowosowopo pelu ijoba ninu adura ki ise ribiribi to n se le maa tesiwaju.

No comments:
Post a Comment