Tolulope Emmanuel
Peter Oluwole eni odun metadinlogbon lowo ileese olopa ilu Ileefe ti te bayii lori esun ole jija.
Peter ni won fesun kan pe o ji okada kan to je ti ileese Dove Security Service lojo kerindinlogbon osu kewa odun yii.
Ni nnkan aago mejo aabo aaro naa la gbo pe Akinola Babatunde wa okada naa lo si Skye Bank to wa lagbegbe Oke-Atan nilu Ileefe.
Bo se gbe okada naa sile ni Peter ta le e to si n salo ko too di pe owo te e.
Inspekito Emmanuel Abdullahi to n soju ileese olopa so pe okada Jincheng AX100 alawo buluu ti Peter ji ohun lo ni nomba Osun QG 06 FFE.
O ni egberun lona ogosan naira ni owo okada ohun, idi niyen ti won fi fi esun meji otooto to nii se pelu idite ati ole jija kan Peter nile ejo.
Abdullahi so pe iwa naa lodi si abala okooledegbeta iwe ofin odun 2002 tipinle Osun n lo.
Nigba ti won ka awon esun mejeeji si Peter leti, o ni oun ko jebi won.
Ninu idajo adajo majistreeti naa, Olalekan Ijiyode gba beeli re pelu egberun lona igba naira pelu oniduro meji ni iye kannaa.
Ijiyode ni okan lara awon oniduro naa gbodo je osise ijoba to si n gbe lagbegbe ile ejo.
O waa sun igbejo siwaju di ojo kejidinlogun osu kejila odun yii.

No comments:
Post a Comment