Yoruba ti won so pe iku akin nii pa akinkanju mo nnkan ti won n so, tori ohun lo difa fun pasito kan to ku sori omo ti won jo n sagbere looteeli.
O pe ti a gbo pe pasito yii ti n fi eebu eyin je iyawo re nisu sugbon oju eeyan Olorun lawon eeyan fi maa n wo o.
Sugbon nnkan yiwo fun un lojo Sannde to koja nigba to ku sori omobinrin omo odun mokandinlogun kan ninu ooteeli nilu Kwale nijoba ibile Ndokwa West nilu Delta.
Gege bi alukoro ileese olopa ipinle naa, DDP Andrew se wi, ariwo ti omodebinrin yen dede pa jade latinuu yaara toun ati pasito ti jo n sere ife lo mu kawon osise oteeli ya lo sibe.
Sugbon nigba ti won yoo fi debe, elemi ti gba a, pasito ti ku patapata.
Won wa nomba foonu iyawo re, iyalenu lo si je fun obinrin naa lati ri oko re nibi to ku si. Oun lo si fi oro naa to awon olopa leti.
DSP Andrew ni iwadi ti bere lori isele naa lati mo nnkan to pa pasito gan an.

No comments:
Post a Comment