Tolulope Emmanuel, Osogbo
Owo ileese olopa ipinle Osun ti te awon omokunrin meji, Micheal Paul ati James Daniel, won si ti foju bale ejo lori esun ole jija.
Gege bi agbejoro to soju ileese olopa lori oro naa, Inspekito Emmanuel Abdullahi se so, inu osu kejo odun yii ni awon olujejo huwa naa lagbegbe Orilonise nilu Ileefe.
Inspekito yii salaye pe se lawon olujejo wolee Ogbeni Jemilo Ojo, ti won si ji oniruuru nnkan nibe .
Lara nnkan ti won ji ni DVD player kan, plasma TV kan, GoTV home theatre kan.
Bakan naa ni won ji bata, aso, baagi nlanla, eni ateeka ati owo to to egberun lona mejilelogun naira, apapo owo nnkan ti won ji ohun si je egberun lona ogoje naira o din eyokan.
Nigba ti won ka esun metewta to nii se pelu igbimopo huwa buburu, ile fido ati ole jija ti won fi kan won, awon mejeeji so pe awon ko jebi.
Agbejoro awon olujejo, Alaba Awoseemo ro ile ejo lati faaye beeli sile fun won pelu ileri pe won ko nii salo fun igbejo nitori won yoo fi oniduro gidi sile.
Ninu idajo re, Majistreeti Olalekan Ijiyode gba beeli won pelu egberun lona ogorun naira ati oniduro meji ni iye kannaa.
O ni okan lara awon oniduro naa gbodo je osise ijoba pelu risiiti iwe owo ori olodun meta ati pe o gbodo maa gbe lagbegbe kootu.

No comments:
Post a Comment