IROYIN YAJOYAJO

Monday, 20 November 2017

LASISI OLAGUNJU: Lati inu ira si ori apata



Tolulope Emmanuel, Osogbo

Bi won ba n so nipa awon ti won ri oore-ofe gba ni irinajo aye won, Dokita Lasisi Olagunju je okan lara won.

Omobibi ilu Eripa nijoba ibile Boluwaduro nipinle Osun ni baba to bi Lasisi sugbon abule kan ti won n pe ni Oyi-Adunni nijoba ibile Ifedayo ni won fi se ibujoko.

Ise agbe ni baba re n se, nigba ti iya re je onisowo obi. Ko si ileewe kankan lagbegbe yen gege bi a se gbo, idi niyii to fi je pe ileekeu loun atawon egbon re lo lasiko to ye ko lo sileewe.

Leyin to lo odun meta ni ileekeu ni anfaani too wa fun un die lati lo sileewe alakobere  labule Oyi-Araromi eleyii to je ibuso mewa si abule won.

Sugbon omode ti yoo ba je Asamu, lati kekere ni yoo ti maa jenu samu-samu. Gbogbo awon akeegbe Lasisi nileewe yen ni won so pe ko si eni to le ba a fori gbari, ko seni to le gba ipokinni mo on lowo titi to fi pari kilaasi mefeefa nileewe alakobere re.

Opolo pipe yii naa lo gbe lo sileewe L.A. Secondary Modern School nilu Ila-Orangun, ko too koja si Agboluaje Grammar School, Ila-Orangun. Gbogbo awon akeegbe re ni won gbagbo pe oro re kii se ojulasan.

Won gbagbo pe juju lo n lo lati fi kawe ati lati fi sedanwo. Koda, a gbo pe awon kan ninuu won dite lojo kan, won si ju iwe to ye ko ka fundanwo sinuu salanga.

Iwe akekobinrin ti won jo wa ninuu kilaasi lo ya lodun naa, iyalenu lo si je fun won pe Lasisi lo tun gbagbe oroke. Esi idanwo asekagba ileewe giga re je eyi ti ko tii siru e ri lagbegbe to ti wa.

Ko sagbara mo nitori Lasisi ko ni alafeyinti kankan to le je iwuri fun un lati te siwaju. Idi niyen to fi gba pe ise oko lo ku koun gbajumo.

Alagba kan lo ri esi idanwo re, iyen lo si pinnu pe iru omo bee ko gbodo ku togotogo. O fun Lasisi ni leta lo sodo oga kan nileewe Gbogbonise ilu Ibadan, eleyii ti eka re wa nilu Iree, ibe lo si ti keko nipa oja tita (Marketing).

Sebi baa ti waye paa maa ri, bee laa ri, Lasisi ko lo odun kan nibe to fi ri anfaani lati wo ileewe Obafemi Awolowo ilu Ileefe nibi to ti keko nipa ede oyinbo (English).

First Class Honours ni Lasisi gbe kuro nileewe naa. O sinru ilu nipinle Sokoto nibi to tun ti tayo. O gba awoodu agunbaniro to se daada ju nipinle naa, bee lo si tun gba tijoba apapo.

Leyin eyi lo darapo mo oselu, o gbapoti ibo gege bii alaga nijoba ibile Ifedayo, gbogbo eeyan lo mo pe Lasisi lo wole sugbon awon kan gbe ote dide, won si da ibo yen ru.

Ori tun so o di amugbalegbe fun alaga ijoba ibile Ifedayo nibi to ti salabapade ololufe re, Alhaja Nimota Olagunju eni to je akowe iroyin funjoba ibile ohun nigba naa.

Nigba ti ijoba Gomina Olagunsoye Oyinlola bere nipinle Osun lodun 2003, pelu awamaridi oore-ofe Olorun lori ayee re, Lasisi di olori eka iroyin funjoba.


Pelu gbogbo wahala ise yen naa lo bere ipele keji ikekogboye re, iyen Masters Degree ni yunifasiti Ibadan. Nipase iforiti, ifayaran ati ipinnu okan, Lasisi ma pari eko yii, lo ba di Dokita nilana ti eko.

Pitimu lawon ojulumo, ore, molebi atawon alabasisepo pe si ileetura Aenon Suite nilu Osogbo lale ojoo Sannde ojo kokandinlogun osu kokanla odun yii lati dawoodunnu pelu okunrin olopolo pipe yii.

Ko si eti to gbo oniruuru oro iwuri to n jade lenu awon eeyan lojo naa ti ko nii gbosuba fun Lasisi, koda lara awon oluko ti won ko o nileewe girama, Comreedi Wale Oyeniyi so pe lati kekere loun ti mo pe akinkanju omo ni.

Lara awon ti won wa nibi ayeye ohun ni Gomina ipinle Osun tele, Omooba Olagunsoye Oyinlola, Gomina Rauf Aregbesola, Alhaji Gboyega Oyetola, Alagba Segun Akinwusi, Oluomo Sunday Akere, Onorebu Lani Baderinwa, Onidajo Jide Falola atiyawo e, Alhaji Kazeem Adio, Alhaji Teslim Igbalaye, Ogbeni Femi Adefila, Barista Tunde Babasola, Barista Leye Falode, Ogbeni Abiola Oloke, Bisoobu Seun Adeoye atiyawo e, Ogbeni Tope Abiola ati bee bee lo.

Lasisi Olagunju konimora, o je akinkanju ninu ohun gbogbo to ba dawole, o si je amuyangan fun gbogbo awon omoleyin re.

No comments:

Post a Comment