Oro leta atejise kan la gbo pe o da wahala sile laarin omo alaga tele fegbe oselu PDP lorileede yii, Alhaji Haliru Bello, Bilyamin atiyawo re, Maryam Sanda, afigba ti Sanda si ran oko e sorun aremabo.
Odun meji seyin la gbo pe Baba Bilyamin fi dandan mu un lati fe Sanda omo oga agba ileefowopamo Aso Savings, bee ni omo kan ti wa laarin won.
Sugbon a gbo pe ko si igbadun kankan ninu igbeyawo naa, a gbo pe onijagidijagan ni Sanda ati pe kii se daada sawon molebi oko re.
Sanda ti koko ge eti oko e je laipe yii to je pe osibitu ni won gbe e lo funtoju. Koda awon molebi so fun un pe ko koyawo e sugbon yi ko yii gbe igbese lori e.
Leyin to kuro losibitu la gbo pe Sanda tun ba leta atejise kan lorii foonu e, aarin oru la gbo pe Sanda gun oko e lobe laya ati ni itan. Nigba to rii pe oro fee yiwo lo sare gbe e lo sileeqosan nla kan ni Maitama, sugbon aso ko ba omoye mo, Bilyamin ti jade laye.




No comments:
Post a Comment