IROYIN YAJOYAJO

Wednesday, 6 December 2017

Ewon osu meta ni Bamidele to jale ni Modakeke n lo o


Tolulope Emmanuel, Osogbo

Lati le je eko fawon odokunrin ti won ti yan ise ole jija laayo, adajo majistreeti kan nilu Modakeke ti pase pe ki Adeyeye Bamidele loo se odun tuntun to n bo yii ninu ogba ewon.

Esun ile jija ti won fi kan Bamidele omo odun metalelogun ni won beere boya o jebi e, sugbon kia lo dahun pe oun jebi.

Bamidele, eni to n gbe lagbegbe Iraye nilu Modakeke lo n jejo esun ile fifo ati ole jija.
Sajenti Ona Glory to n soju ileese olopa lori esun naa salaye pe lojo karun osu kokanla odun yii ni Bamidele huwa naa ni nnkan aago meji osan.

Agbegbe Uncle D lopopona Toro nilu Modakeke la gbo pe Bamidele lo, to si wonu ilee Arabinrin Owolabi Gladys.

O ni egberun lona merindinlogoji naira ni Bamidele ko ninu ile ohun eleyii ti ni o tako ofin iwa odaran tipinle Osun.

Sugbon inu bi adajo majistreeti naa, Bose Awosan pelu bi Bamidele se n se ninuu kootu. Adajo yii ni o han gbangba pe olujejo ko kabamo nnkan to se rara.

Awosan ni lati le je eko fawon odo bii tie, oun ko gbodo faaye beeli sile fun un. 

O waa pase pe ki won loo fi Bamidele pamo sogba ewon fun osu meta gbako laifaaye faini sile fun un rara.

No comments:

Post a Comment