Ogbeni Biodun Bashir to n sise pelu ajo Universal Basic Education (UBE) nipinle Kwara ti pokunso bayii.
Ironu aigbowo osu lati opolopo osu seyin la gbo pe o fa a ti okunrin ti gbogbo eeyan mo si Legal naa fi binu gbemi araa re lojoo Satide to koja.
Dereba ajo UBE nijoba ibile Oyun nipinle Kwara lokunrin naa titi di ojo to gbemi araa re ohun.
Gege bi Ogbeni Abdulrasaq O. Hamzat to je oludari egbe Kwara must Change se so, ibanuje nla niku Legal je nitori ona to gba waye.
O ni pelu bijoba ipinle Kwara se n paro fawon eeyan pe oun ko je owo osu, ibanuje lo je lati rii pe osise abee re pokunso nigba ti ko ri ona abayo.
No comments:
Post a Comment