Tolulope Emmanuel, Osogbo
Igbakeji gomina ipinle Osun nigba kan ri, Otunba Iyiola Omisore ti so pe edun okan ni iku akobikunrin fundile Asiwaju Bola Ahmed Tinubu je fun oun, oun si mo pe Olorun nikan lo le tu idile naa ninu niru asiko bayii.
Bakan naa ni akowe agba funjoba ipinle Osun tele, to tun je asiwaju ninu egbe oselu Labour Party, Alhaji Fatai Akinbade so pe iroyin iku naa ba oun lojiji ati pe alafo nla ni iku Barista Jide Tinubi fi sile ninu idile re ati lawujo awon agbejoro lorileede yii.
Ninu atejade ti Osun Renewal Agenda (ORA) ti inagije won n je Akinbade's Ambassador fi sita loruko Alhaji Akinbade ni won ti sapejuwe Oloogbe Jide Tinubu gege bii odokunrin ti ojo-ola re dara latari bo se jafafa lenu ise to yan laayo.
Gege bi adari egbe ORA, Arakunrin Omotunde Stephen Adekunle se so, afi ki Asiwaju Tinubu atidile re fi okan won sodo Olorun niru asiko yii nitori Oun nikan ni aseyiowuu.
Otunba Iyiola Omisore naa sapejuwe iku to pa Jide gege bi eyi to ba tonile talejo lojiji, ti ko si seni to le ronu iru e laelae.
O waa gbadura pe ki Olorun tu idile ti Jide Tinubu fi sile ninu, ki Olorun si dawo ibi duro.
No comments:
Post a Comment