Tolulope Emmanuel, Osogbo
Ti iroyin to n lo lowo bayii ba je ooto, a je pe Apetumodu ti ilu Ipetumodu, Oba James Adegoke, Akunraaledoye Keta ti darapo mo awon babanlaa re.
Oba Adegoke, eni to ti le logorin odun la gbo pe o waja lojo meji seyin. Oluko agba nileewe alakobere ni baba, bakan naa ni won je akonimoogba egbe agbaboolu ki won too dori oye babanlaa won.
Nnkan osu meji seyin ni awon oba alaye meji, Salu ti Eduabon ati Olulamokun ti Yakooyo nijoba ibile Ariwa Ife kannaa waja.

No comments:
Post a Comment