IROYIN YAJOYAJO

Monday, 25 December 2017

Adura ati isokan lorileede yii nilo bayii - Alhaji Adeoti


Tolulope Emmanuel, Osogbo

Akowe agba funjoba ipinle Osun, Alhaji Moshood Adeoti ti ro gbogbo awon omo orileede yii lati tubo kun fun adura funjoba egbe oselu APC.

Ninu oro odun keresimesi ti Adeoti fowosi lo ti ni ko si nnkan kan to ye ko je gbogbo awon omo orileede yii logun ju bi isokan yoo se tubo maa gbile sii lo.

Adeoti ni eko ife to je pataki odun keresimesi lo ye ki gbogbo awon eeyan mu lo, paapa pelu oniruuru ipenija to n koju orileede yii bayii.

O ni fungba die ni gbogbo ipenija naa ku, ati pe pelu adura ati ifowosowopo awon omo orileede yii, ohun gbogbo yoo bo sipo.

Bakan naa lo ro awon eeyan ipinle Osun lati fowosowopo pelu ijoba to wa lode bayii, ki won si maa ri awon ise idagbasoke to ti se eleyii to ni ko tii si iru re ri l'Osun.

No comments:

Post a Comment