IROYIN YAJOYAJO

Saturday, 23 December 2017

Awon abanije ni won wa nidi foto mi ti won n gbe kiri bayii -Abenugan Salam


Tolulope Emmanuel, Osogbo

Abenugan ile igbimo asofin ipinle Osun, Onorebu Najeem Salam ti ni ise owo awon asebaje ni foto kan nibi ti oun ti n pin Tii-Olokun ati Gala ti  won n gbe kiri bayii.

Salam salaye fun Nje e ti gbo pe lasiko ipolongo atundi ibo Gomina Aregbesola  lodun 2014 loun ti ya foto naa.

O ni okan lara awon ololufe oun to tun feran isejoba Gomina Aregbesola lo ko awon nnkan naa wa lopo yanturu pe koun maa pin fun awon eeyan nigba naa lati fi moriri ife ti won ni sijoba egbe APC l'Osun.

Salam ni oun mo pe ero buburu lawon ti won loo hu foto naa jade lasiko yii ni sugbon Olorun ti gbe oun borii won.

O ni o ti to osu kan bayii toun ti de ilu oun l'Ejigbo gbeyin, o salaye pe ojoo Monde ose yii loun sese de lati oke-okun toun lo ati pe ojo Tusde loun tun ti forile Abuja funpade pelu awon gomina, toun si pade de si Osogbo lojoo Wesde fun ayeye odun keresimesi to waye nibe

Salam ni o ya oun lenu bi won se so pe se loun n fi Tii-olokun ati Gala naa ki awon eeyan oun nilu Ejigbo kaabo latilu oyinbo toun lo.

No comments:

Post a Comment