IROYIN YAJOYAJO

Saturday, 23 December 2017

L'Ondo, Kabiesi lu awon ijoye ni jibiti, ladajo ba ju u sewon odun meji


Adajo ile ejo majistreeti kan nijoba ibile Odigbo nilu Ore nipinle Ondo ti ni ki Akamuja ti Igburowo loo faso penpe roko oba fun odidi odun meji gbako.
Crown
A oo ranti pe awon eeyan ilu Igburowo ti fehonuhan nipa awon iwa ti ko bojumu ti won ni kabiesi naa n hu lodun 2012.
Bakan naa nijoba ipinle Ondo ti figba kan so pe ki kabiesi naa loo rookun nile ko too di pe awon kan ba a bebe lodo ijoba nigba naa.
Sugbon se ni won ni kabiesi yii tun lu awon ijoye e ni jibiti nipa kiko owo to to si won sinuu akanti araa re.
Esun merindinlogoji ni won fi kan oba yii, bee ni ile ejo so pe o jebi won.
Lara awon esun ohun ni ole jija, siso owo osu awon ijoye atawon osise di tara eni, pipe ara eni ni nnkan ti a ko je ati bee bee lo.
Ninu idajo re, Ogbeni O.J. Adelegan ni o dabi eni pe kabiesi naa ko ni eri-okan, bee ni ko loroo gbo, o waa ni ki kabiesi naa da owo to le legberun lona irinwo pada fun ilu Igbulowo.
Lori esun ole jija, adajo ju kabiesi naa sewon odun meji, lori esun kiko owo awon ijoye, won ju u sewon odun meji tabi ko san faini egberun lona eedegbeta naira. Bakan naa ladajo ni ko san egberun lona eedeta naira fun faini esun pipe ara eni lohun ti a ko je.

No comments:

Post a Comment