IROYIN YAJOYAJO

Friday, 15 December 2017

Awon oniroyin ni won n ta awon omo orileede yii soko eru nile okeere - Aragbiji


Tolulope Emmanuel, Osogbo

Aragbiji ti ilu Iragbiji, Oba Abdulrasheed Olabomi ti so pe awon oniroyin gan an lebi lorii bi opolopo odo orileede yii se n ko sowo awon akonisise loke okun.

Ilu Osogbo ni Aragbiji ti soro naa laipe yii.

Kabiesi ni bi awon oniroyin se n fi gbogbo igba polowo oniruuru anfaani to si sile loke okun wa lara awon nnkan to n mu ki ife awon odo fa si oke-okun.

O ni opolopo anfaani yii si lawon oyinbo ti won waa polowo won lorileede yio ko nii jewo itakun to wa nidi okookan won.

Oba Olabomi ni o ye ki ajo to n ri si gbogbo eto to n jade lafefe lorileede yii, iyen NBC gbesele pipolowo irinajo sawon orileede to kaakiri agbaye, o ni tawon odo ko ba gbo awon ikede yii mo, okan won a maa si kuro nibi irinajo lo soke okun diedie.

No comments:

Post a Comment