Omokunrin eni odun meedogbon kan, Moses Opalere la gbo pe o ti dero orun apapandodo bayii leyin to mu ogogoro igo mesan.
Moses ati ore re, Lasisi ni won jo lerii siraa won lori eni to le mu ogogoro julo laarin awon mejeeji, bee ni Lasisi si ko egberun merin naira kale fun ifigagbaga naa.
Won bere ogogoro mimu loooto lagbegbe Anko nilu Eruwa nipinle Oyo sugbon nigba ti Moses mu ogogoro de ori igo mesan, oro yiwo, ko mo nnkan to n se mo.
Lasisi la gbo pe o mu un lo silee re ti ko jinna sibi ti won wa, o gbe beedi fun un sita pe ko sun ki afefe le fe sii sugbon oju oorun ohun la gbo pe o gba de oju iku.
Iwadi fi han pe awon olopa ti bere iwadi lori isele naa, awon eeyan bii mewa lowo si ti te lori e.
No comments:
Post a Comment