Tolulope Emmanuel, Osogbo
Rotimi Adedapo, eni ti won fesun kan pe o lu enikan ni jibiti milioonu meta naira ladajo ti pase pe ki won loo fi pamo sogba ewon bayii.
Aago mokanla aaro ojo kejidinlogbon osu kesan odun yii la gbo pe Rotimi, eni odun mejidinlaadota gba owo ohun lowoo Bunmi Alabetutu.
Se ni Rotimi so fun Alabetutu pe oun yoo ta ile olojule mewa kan fun un sugbon ti oro pada ja si jibiti.
Gege bi Sajenti Glory Ona to duro funleese olopa se so, se ni Rotimi gba owo naa, to si fi gbo bukata ti araa re laita ile fun Alabetutu mo.
Femi Opadare to je agbejoro fun olujejo beere fun beeli re leyin to so pe oun ko jebi esun jibiti lilu ti won fi kan an.
Opadare seleri funle ejo pe olujejo ko nii salo fun igbejo ati pe o setan lati fi awon oniduro to loruko lawujo sile.
Sugbon adajo majistreeti naa, Bose Awosan ni oun ko lee faaye beeli sile fun un ayafi ti agbejoro won ba se ohun to to labe ofin nipa mimu iwe wa fun beeli olujejo.
O waa pase pe ki olujejo lo maa se faaji logba ewon naa titi ti igbejo yoo fi bere lori oro e.
No comments:
Post a Comment