Tolulope Emmanuel, Osogbo
Bii igba teeyan n wo fiimu Babaajesa loro naa ri fun Gomina Aregbesola atawon omo igbimo re laipe yii nigba tawon adari egbe osise ijoba nipinle Osun yari kanle pe awon ko je amala ati iresi tijoba se kale fawon, owo osu lawon fee gba.
Ipade ifikunlukun kan ni gomina pe awon eeyan ohun si, won si ti te tabili ounje sile repete niwajuu won, sugbon se lawon osise ohun fariga pe awon ko ba ti ounje wa, oro owo osu lawon waa yanju.
Ki gomina too mo nnkan to sele, awon osise ohun ti n jade leyokookan, koda, gbogbo arowa olori awon osise ijoba nipinle Osun, Dokita Olowogboyega Oyebade pe ki won tie meran je ni ko wo won leti, won lawon o jeun.
Ohun to si fa eleyii, gege bi a se gbo, ni waasi ti gomina tun n ro fawon eeyan yii pe se ni ki won tun ni suuru fungba die si, o ni ki won foriti idaji owo osu ti won n gba nitori eto oro aje ipinle Osun ko tii se daada.
Sebi losu meta seyin lawon osise ohun fun Aregbesola ni gbedeke ipari osu kokanla lorii bo se n kun owo osu mo won lowo, won ni odidi owo lawon fee maa gba bere lati osu yii lo.
Idi niyii tijoba fi pe won sipade laipe yii, to si je pe itan kannaa ti won ti n gbo lati odun meji seyin nijoba tun n so fun won, bee ni won ti file ponti fona roka sile kawon yen too yari pe awon kii se olounje iya.
Ni bayii, oro iyanselodi n kanlekun l'Osun nitori igbakuugba la gbo pe awon osise ohun le bere.
Wednesday, 20 December 2017
Home
/
iroyin
/
iroyin-agbegbe
/
Awon osise yari f'Aregbesola; 'Awa o j'amala nilee re mo, ekunrere owo osu la fee gba'
Awon osise yari f'Aregbesola; 'Awa o j'amala nilee re mo, ekunrere owo osu la fee gba'
Tags
# iroyin
# iroyin-agbegbe
.Njeetigbo
.
iroyin-agbegbe
Labels:
iroyin,
iroyin-agbegbe
Subscribe to:
Post Comments (Atom)
No comments:
Post a Comment