Tolulope Emmanuel, Osogbo
Inu iporuru okan ni awon banki ti won ya ijoba ipinle Osun labe idari Gomina Rauf Aregbesola lowo wa bayii latari bi ile ejo giga ipinle Osun to wa nilu Ilesa se ni ko si nnkan to n je State of Osun ninu ofin orileede yii.
Kii se awon banki nikan o, bee ni gbogbo awon kongila ti won gba ise labe adehun State of Osun ko tii mo ohun ti yoo je atubotan egbeelegbe bilioonu naira tijoba je won.
Odun 2011 ni Gomina Aregbesola dede sekede pe ipinle Osun ko nii je Osun State to n je latigba ti won ti da a sile mo bikose State of Osun.
Sugbon lodun to koja ni agbejoro kan nipinle Osun, Barista Kanmi Ajibola forile ile ejo giga ilu Ilesa nigba tileese kan dede mu owo goboi lo fun un gege bii owo ori ti yoo san funjoba labe oruko State of Osun.
Ebe meje otooto ni Ajibola gbe lo siwaju ile ejo, lara re ni pe kile ejo pase pe ko si nnkan to n je State of Osun ninu iwe ofin. Bakan naa lo ni ileese kankan ko leto lati maa gba owo ori funjoba laije pe komisanna feto isuna mo si, bee ijoba ko tii yan komisanna nigba naa.
Bakan naa ni Ajibola ni kile ejo so pe gbofbo ofin tawon omo ile igbimo asofin se labe State of Osun ko lee ribi joko.
Komisanna feto idajo l'Osun, Dokita Basiru Ajibola naa ja fitafita lati so pe ko si nnkan to buru ninuu bi oga re se yi oruko ipinle Osun pada losan kan oru kan.
Sugbon nigba idajo oniwakati kan re, Onidajo Yinka Afolabi so pe iwa aibowo ati ainaani ofin ni Gomina Aregbesola hu pelu bo se sayipada oruko ipinle Osun.
O ni ko si nnkan to n je State of Osun ninu ofin orileede Naijiria ati pe igbese adabowo ti ko lese nile ni oro naa je.
Onidajo ohun ni kii se oruko State of Osun ni won fi bura fun awon asofin ipinle Osun ti won n huwa to lodi si ofin bayii.
O ni labe ofin, leyin ti won ba ti bura fun eeyan labe oruko kan, eni naa ko leto lati yi oruko naa pada rara. O ni oruko ipinle jinle koja ohun tenikan yoo dede joko sibikan lati yipada.
Onidajo Afolabi waa dajo pe otubante ati imulemofo ni oruko ati ohun gbogbo tijoba ti se labe State of Osun.
Bo tile je pe Dokita Ajibola ni ijoba yoo pe ejo kotemilorun lori idajo naa, sibe jinnijinni ti ba awon banki nlanla ti won yajoba lowo nitori ko si bi won yoo se ri owo ti won ko sile labe State of Osun gba lowoo Osun state.
No comments:
Post a Comment