Tolulope Emmanuel, Osogbo
Lara awon ona tijoba ipinle Osun fi n mu igbe-aye irorun ba awon araalu, Gomina Aregbesola tun ti seto oko oju-irin ofe fun awon omobibi ipinle Osun ti won fe waa se odun nile latipinle Eko.
Gege bi komisanna feto okoowo ati egbe alajeseku nipinle Osun, Ogbeni Ismail Adekunle Alagbada se so ninu atejade kan, ojo ketalelogun osu yii ni oko oju irin akooko yoo gbera lati Ido Terminus ni Ebute-Meta fun ayeye odun keresimesi.
Aago mewa owuro ojo satide ohun ni yoo gbera, yoo si pada si Eko lojoo Tusde, ojo kerindinlogbon osu kejila yii bakan naa.
Jayeoba-Alagbada fi kun oro re pe irin ajo eleekeji fun oko ojuurin naa yoo waye logbonjo osu kejila lati Ido Terminus ni Ebute-meta laago mewa owuro, yoo si tun pada si Eko lojo keji osu kinni odun to n bo.
O ni lati odun 2011 ti awon araalu ti eto naa ti bere, o ti to awon eeyan egberun lona aadofa ti won ti janfaani re.
Alagbada waa ro awon ara ipinle Osun atawon ipinle alamulegbe ti won n gbe nilu Eko lati lo anfaani naa daradara.
Thursday, 21 December 2017
Home
/
iroyin
/
iroyin-agbegbe
/
Ayeye odun Keresimesi: Aregbesola seto oko oju-irin ofe fawon araalu
Ayeye odun Keresimesi: Aregbesola seto oko oju-irin ofe fawon araalu
Tags
# iroyin
# iroyin-agbegbe
.Njeetigbo
.
iroyin-agbegbe
Labels:
iroyin,
iroyin-agbegbe
Subscribe to:
Post Comments (Atom)
No comments:
Post a Comment