Igbakeji gomina funpinle Osun tele, Otunba Iyiola Omisore ti so pelu idaniloju pe wahala to n fi egbe oselu PDP nipinle Osun logbologbo yoo rokun igbagbe laipe yii.
Koda, Omisore ni laarin osu kan pere si asiko yii ni isele nla yoo sele ninu eyi ti ogun eleyameya yoo wa sopin ninu egbe PDP.
A oo ranti pe egbe naa ti pin si meji nipinle Osun, Dokita Faforiji lo n dari awon iko kan ninu eyi ti Seneto Omisore wa, nigba ti Onorebu Soji Adagunodo ko awon kan sodi.
Sugbon lasiko ti Omisore n ki awon kan ti won kuro lodo Adagunodo bo sodo Faforiji kaabo lo ti ni agbo to feyin rin loro egbe naa yoo je nipinle Osun nitori pe tagbaratagbara lawon n pada bo bayii.
Omisore fi kun oro re pe ko si egbe oselu miin to tun le yo awon eeyan ipinle Osun ninu igbekun tijoba egbe oselu APC fi si bayii yato si egbe PDP.
O tun lo asiko naa lati pin iresi odun fun gbogbo woodu to wa nipinle Osun eleyii to ni oun se lati fi derin peeke awon eeyan naa.
Bee lo tun seleri lati se sii laipe yii paapa fun awon osisefeyinti ati awon osise ijoba l'Osun ti owo osu won ko se deede lowolowo bayii.
No comments:
Post a Comment