Tolulope Emmanuel, Osogbo
Alaga ajo to n mojuto oro ijoba ibile l'Osun, Dokita Peter Adebayo Babalola ti so pe arameeriri lawon ise idagbasoke ti Gomina Rauf Aregbesola ti se nipinle Osun laarin odun meje to ti lo.
Babalola ni ilu Osogbo to je olu ilu ipinle Osun ko yato si ijoba ibile lasiko ti Aregbesola gbajoba ko too waa tunpinle Osun so bii eni so igba.
Lasiko ti Babalola n gbalejo egbe awon asojukoroyin nipinle Osun nilee re to wa nilu Ikire lo ti so pe apewaawo ni oniruuru ise akanse ti Aregbesola ti se l'Osun.
Asiwaju ninu egbe oselu APC ohun so pe awon oniroyin o tii se ojuse won nipa pipolongo awon ise Aregbesola rara nitori opolopo nnkan to le je awokose fawon ipinle miin ni Gomina Aregbesola n se.
O so siwaju sii pe oniruuru iro ati oro ibanilorukoje lawon eeyan n so kaakiri nipa owo osu awon osise eleyii to ni ko si ooto kankan nibe.
Babalola waa ro awon oniroyin lati gbaruku tijoba Aregbesola ninuu gbogbo idawole re nitori ijoba re ti se gudugudu meje kaakiri ipinle Osun.
Wednesday, 6 December 2017
Home
/
iroyin
/
iroyin-agbegbe
/
iroyin-oselu
/
Ko tii sijoba to gbiyanju l'Osun bii ijoba Aregbesola - Peter Action
Ko tii sijoba to gbiyanju l'Osun bii ijoba Aregbesola - Peter Action
Tags
# iroyin
# iroyin-agbegbe
.Njeetigbo
.
iroyin-oselu
Labels:
iroyin,
iroyin-agbegbe,
iroyin-oselu
Subscribe to:
Post Comments (Atom)

No comments:
Post a Comment