Tolulope Emmanuel, Osogbo
Kayeefi loro ohun je fawon eeyan agbegbe Zone 5 loju ona Ajetumobi ni Eko-Ende nilu Ikirun nijoba ibile Ifelodun nipinle Osun nigba ti won dede gbo pe omokunrin kan be iyaa re lori.
Loooto ni gbogbo awon ti won wa lagbegbe naa ti mo tele pe omokunrin eni odun metadinlogun ohun, Joseph Mark ni arun opolo tele sugbon won ko mo pe o lagbara debii pe o le gbemi iya re.
Ko si wahala kankan rara nigba tawon idile naa ji laaro ojo Sannde to koja yii, sugbon won ko mo pe satani yoo juko ibanuje sinu ile naa ki ile too su.
Joseph to je akekojade ni Adekunle Ajasin University yo wa nipinle Ondo ati iya re, Christianah Mark eni odun mejilelogota la gbo pe o wa ninu ile ni nirole ojo nla yii, sugbon nigba yo fi maa di aago mefa irole ni oro yiwo.
Okan lara awon egbon Joseph to n je Adewale lo dede ke gbajare fawon araadugbo nigba to dede ba iya won ninu agbara eje, to si ri ada to kun fun eje, bee ni Joseph yo sise naa ko salo, oun naa duro sinu ile.
Gege bi Adewale se wi, ko si wahala kankan toun fi kuro ninu ile ni nnkan ogbon iseju sigba tisele naa sele, oun si fi Joseph ati iyaa won sile ninu ile.
Gbogbo ibeere ti won n beere lowoo Joseph lorii ohun to ri lobe to fi ro o pe bibelori lo kan fun iya re ni ko fun enikeni lesi, o kan n wo won ni.
Bayii ni Adewale yara lo si ago olopa to wa nilu Ikirun lati fi to won leti, awon olopa sare waa fi pampe oba mu Joseph lo sago won.
Bee ni won si gbe oku iya naa lo sile igbokupamosi aladani kan, Paradise Private Mortuary to wa nilu Ikirun.
Komisanna funleese olopa nipinle Osun, Adeoye Fimihan fidi isele naa mule, o si ni iwadi si n lo lowo lori isele naa.

No comments:
Post a Comment