Ojoo Fraide ose yii, iyen ojo kejilelogun osu kejila yii ni asofin to n soju awon eeyan agbegbe Ariwa Ife nile igbimo asofin ipinle Osun, Onorebu Tunde Olatunji yoo seto ironilagbara fun eedegbeta eeyan lagbegbe ohun.
Nibi eto naa, eleyii ti yoo waye ninuu gbongan ilu Ipetumodu laago mewa aaro ojo naa ni Onorebu Olatunji yoo ti derin peeke awon opo pelu awon omo orukan.
Bakan naa ni asojusofin yii yoo tun seto iranlowo fun awon agbe, awon onise owo, awon odo, awon arugbo pelu awon olokoowo kekeke.
Gege bi Olatunji se wi, eto naa wa lara awon ileri to se fawon eeyan ti won dibo fun un lati mu ereje ijoba tiwantiwa de enu ona won.
O waa ro gbogbo awon toro kan lati tete de sibi eto naa.
No comments:
Post a Comment