IROYIN YAJOYAJO

Thursday, 14 December 2017

Isejoba PDP ati APC ti su awon omo orileede yii - Doyin Okupe


Tolulope Emmanuel, Osogbo

Asaaju kan ninu egbe oselu Accord Party ti so pe ijakule nla lawon omo orileede yii ba pade ninu isejoba egbe oselu APC ati PDP.

Okupe, eni to ti figba kan ri je oluranlowo pataki fun Aare Goodluck Jonathan so pe ko siyato kankan laarin egbe oselu PDP ati APC.

Nilu Osogbo lo ti soro yii lasiko ipade apero kan ti egbe Accord se lose to koja. Okupe ni gbogbo ariwo iyipada ti egbe oselu APC n pa ko so eso rere kankan nitori pe awon araalu ko tii ri anfaani kankan je latara egbe naa.

Ni ti idibo gomina to n bo lona nipinle Osun, Okupe ni agba ofifo lo maa n pariwo, o ni eso-eso ti ejo n gun ope lawon yoo fi oro naa se titi ti egbe oselu Accord yoo fi wole gege bii gomina losun lodun to n bo.

O ni eredi lilo kaakiri awon asaaju egbe naa lasiko yii ni lati ta awon omo egbe ji kaakiri awon ipinle lori awon idibo olokanojokan to n bo lona.

Okupe ni egbe oselu Accord nikan lo fi anfaani sile fawon odo lati dije, yato si awon arugbo tawon egbe oselu yooku n gbe kale.

Ninu oro tire, alaga egbe Accord l'Osun, Olusegun Fanibe ro awon omo egbe lati seraa won lokan fun idagbasoke egbe naa.

Fanibe ni ti gbogbo awon omo egbe ba le gbiyanju lati sise daada, yoo ro won lorun lati gbajoba ipinle yii ati orileede yii lapapo.

No comments:

Post a Comment